Matthew 19:16-30

Ọ̀dọ́mọkùnrin ọlọ́rọ̀

16 a bẸnìkan sì wá ó bí Jesu pé, “Olùkọ́, ohun rere kí ni èmi yóò ṣe, kí èmi kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun?”

17Jesu dá a lóhùn pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń béèrè nípa ohun rere lọ́wọ́ mi. Ẹni kan ṣoṣo ni ó wà tí í ṣe Ẹni rere. Bí ìwọ bá fẹ́ dé ibi ìyè, pa àwọn òfin mọ́.”

18 cỌkùnrin náà béèrè pé, “Àwọn wo ni òfin wọ̀nyí?”

Jesu dáhùn pé, “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn; Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà; Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè; Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké’,
19bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ. ‘Kí o sì fẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’ ”

20Ọmọdékùnrin náà tún wí pé, “Gbogbo òfin wọ̀nyí ni èmi ti ń pamọ́, kí ni nǹkan mìíràn tí èmi ní láti ṣe?”

21 dJesu wí fún un pé, “Bí ìwọ bá fẹ́ di ẹni pípé, lọ ta ohun gbogbo tí ìwọ ní, kí o sì fi owó rẹ̀ tọrẹ fún àwọn aláìní. Ìwọ yóò ní ọrọ̀ ńlá ní ọ̀run. Lẹ́yìn náà, wá láti máa tọ̀ mi lẹ́yìn.”

22Ṣùgbọ́n nígbà tí ọ̀dọ́mọkùnrin náà gbọ́ èyí, ó kúrò níbẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́, nítorí ó ní ọrọ̀ púpọ̀.

23 eNígbà náà, ní Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, ó ṣòro fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọ̀run.” 24Mo tún wí fún yín pé, “Ó rọrùn fún ìbákasẹ láti wọ ojú abẹ́rẹ́ jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run.”

25Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn gbọ́ èyí, ẹnu sì yà wọn gidigidi, wọ́n béèrè pé, “Ǹjẹ́ ta ni ó ha le là?”

26 fṢùgbọ́n Jesu wò wọ́n, ó sì wí fún wọn pé, “Ènìyàn ni èyí ṣòro fún; ṣùgbọ́n fún Ọlọ́run ohun gbogbo ni ṣíṣe.”

27 gPeteru sì wí fún un pé, “Àwa ti fi ohun gbogbo sílẹ̀, a sì tẹ̀lé ọ, kí ni yóò jẹ́ èrè wa?”

28 hJesu dáhùn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, ‘Nígbà ìsọdọ̀tun ohun gbogbo, nígbà tí Ọmọ Ènìyàn yóò jókòó lórí ìtẹ́ tí ó lógo, dájúdájú, ẹ̀yin ọmọ-ẹ̀yìn mi yóò sì jókòó lórí ìtẹ́ méjìlá láti ṣe ìdájọ́ ẹ̀yà Israẹli méjìlá. 29Àti pé ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ilé tàbí arákùnrin tàbí arábìnrin tàbí baba tàbí ìyá tàbí àwọn ọmọ, tàbí ohun ìní rẹ̀ sílẹ̀ nítorí orúkọ mí, yóò gba ọgọọgọ́rùn-ún èrè rẹ̀ láyé, wọn ó sì tún jogún ìyè àìnípẹ̀kun. 30Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn tí ó síwájú nísinsin yìí ni yóò kẹ́yìn, àwọn tí ó kẹ́yìn ni yóò sì síwájú.’

Copyright information for YorBMYO